Angẹli kẹta da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu odò ati sinu ìsun omi, ó bá di ẹ̀jẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn angẹli tí omi wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tí ó sọ pé, “Olódodo ni ọ́ fún ìdájọ́ rẹ wọnyi, ìwọ tí ó wà, tí ó ti wà, ìwọ Ẹni Mímọ́! Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati àwọn wolii rẹ sílẹ̀, nítorí náà o fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ohun tí ó yẹ wọ́n ni o fún wọn!” Mo bá gbọ́ tí pẹpẹ ìrúbọ wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, Ọlọrun, Olodumare, òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ.”
Kà ÌFIHÀN 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌFIHÀN 16:4-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò