ÌFIHÀN 16:1-21

ÌFIHÀN 16:1-21 YCE

Mo gbọ́ ohùn líle kan láti inú Tẹmpili tí ó sọ fún àwọn angẹli meje náà pé, “Ẹ lọ da àwọn àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun sinu ayé.” Angẹli kinni lọ, ó bá da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu ayé. Ni egbò rírà tí ń rùn bá dà bo àwọn tí wọ́n ní àmì ẹranko náà ní ara, tí wọ́n sì ń júbà ère rẹ̀. Angẹli keji da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu òkun, ni òkun bá di ẹ̀jẹ̀, bí ẹ̀jẹ̀ ara òkú, gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí tí ó wà ninu òkun sì kú. Angẹli kẹta da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu odò ati sinu ìsun omi, ó bá di ẹ̀jẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn angẹli tí omi wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tí ó sọ pé, “Olódodo ni ọ́ fún ìdájọ́ rẹ wọnyi, ìwọ tí ó wà, tí ó ti wà, ìwọ Ẹni Mímọ́! Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati àwọn wolii rẹ sílẹ̀, nítorí náà o fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ohun tí ó yẹ wọ́n ni o fún wọn!” Mo bá gbọ́ tí pẹpẹ ìrúbọ wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, Ọlọrun, Olodumare, òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ.” Angẹli kẹrin da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ nù sórí oòrùn, a bá fún un lágbára láti máa jó eniyan bí iná. Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí jó àwọn eniyan bí iná ńlá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun tí ó ní àṣẹ lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọnyi, dípò kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n fi ògo fún un. Angẹli karun-un da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà, ó bá sọ ìjọba rẹ̀ di òkùnkùn. Àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí gé ara wọn láhọ́n jẹ nítorí ìrora wọn, wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun ọ̀run nítorí ìrora wọn ati nítorí egbò ara wọn, dípò kí wọ́n ronupiwada fún ohun tí wọ́n ti ṣe. Angẹli kẹfa da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sórí odò ńlá tí wọn ń pè ní Yufurate, ni omi rẹ̀ bá gbẹ láti fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọba tí ń bọ̀ láti ìhà ìlà oòrùn. Mo wá rí àwọn ẹ̀mí burúkú mẹta kan, wọ́n dàbí ọ̀pọ̀lọ́ ní ẹnu Ẹranko Ewèlè náà, ati ní ẹnu wolii èké náà. Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ. “Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.” Ó bá kó àwọn ọba wọnyi jọ sí ibìkan tí ń jẹ́ Amagedoni ní èdè Heberu. Angẹli keje da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Ẹnìkan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ láti ibi ìtẹ́ tí ó wà ninu Tẹmpili, ó ní, “Ó ti parí!” Ni mànàmáná bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ìgbà tí eniyan ti dé orí ilẹ̀ ayé. Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀. Omi bo gbogbo àwọn erékùṣù, a kò sì rí ẹyọ òkè kan mọ́. Yìnyín ńláńlá tí ó tóbi tó ọlọ ata wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu eniyan láti ojú ọ̀run. Àwọn eniyan wá ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí ìparun tí yìnyín yìí ń fà, nítorí ó ń ṣe ọpọlọpọ ijamba.