ÌFIHÀN 12

12
Obinrin kan ati Ẹranko Ewèlè
1Mo wá rí àmì ńlá kan ní ọ̀run. Obinrin kan tí ó fi oòrùn ṣe aṣọ, tí òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dé adé tí ó ní ìràwọ̀ mejila. 2Obinrin náà lóyún. Ó wá ń rọbí. Ó ń jẹ̀rora bí ó ti fẹ́ bímọ.
3Mo wá tún rí àmì mìíràn ní ọ̀run: Ẹranko Ewèlè ńlá kan tí ó pupa bí iná, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá, ó dé adé meje.#Dan 7:7 4Ó fi ìrù gbá ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, wọ́n bá jábọ́ sórí ilẹ̀ ayé. Ẹranko Ewèlè yìí dúró níwájú obinrin tí ó fẹ́ bímọ yìí, ó fẹ́ gbé ọmọ náà jẹ bí ó bá ti bí i tán.#Dan 8:10 5Obinrin yìí bí ọmọkunrin, tí yóo jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè pẹlu ọ̀pá irin. A bá já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun, níwájú ìtẹ́ rẹ̀.#a Ais 66:7; b O. Daf 2:9 6Obinrin yìí bá sálọ sí aṣálẹ̀, níbìkan tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀. Níbẹ̀ ni ó wà lábẹ́ ìtọ́jú fún ẹgbẹfa ọjọ́ ó lé ọgọta (1260).
7Ogun wá bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Mikaeli ati àwọn angẹli rẹ̀ ń bá Ẹranko Ewèlè náà jà. Ẹranko Ewèlè yìí ati àwọn angẹli rẹ̀ náà jà títí,#Dan 10:13, 21; 12:1; Juda:9 8ṣugbọn kò lágbára tó láti ṣẹgun. Wọ́n bá lé òun ati àwọn angẹli rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. 9Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀.#a Jẹn 3:1; b Luk 10:18
10Mo wá gbọ́ ohùn líle kan ní ọ̀run tí ó sọ pé, “Àkókò ìgbàlà nìyí ati ti agbára, ati ìjọba ti Ọlọrun wa, ati àkókò àṣẹ Kristi rẹ̀. Nítorí a ti lé Olùfisùn àwọn onigbagbọ ara wa jáde, tí ó ń fi ẹjọ́ wọn sùn níwájú Ọlọrun wa tọ̀sán-tòru.#Job 1:9-11; Sak 3:1 11Wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan ati ẹ̀rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ṣẹgun rẹ̀. Nítorí wọn kò ka ẹ̀mí wọn sí pé ó ṣe iyebíye jù kí wọ́n kú lọ. 12Nítorí náà, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú wọn. Ó ṣe fun yín, ayé, ati fún òkun! Nítorí Èṣù ti dé sáàrin yín. Inú rẹ̀ ń ru, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni ó kù fún òun.”
13Nígbà tí Ẹranko Ewèlè náà rí i pé a lé òun jáde sinu ayé, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé obinrin tí ó bí ọmọkunrin nnì kiri. 14Ni a bá fún obinrin náà ní ìyẹ́ idì ńláńlá meji, kí ó lè fò lọ sí aṣálẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ó fi bọ́ lọ́wọ́ ejò náà.#Dan 7:25; 12:7 15Ni ejò yìí bá tú omi jáde lẹ́nu bí odò, kí omi lè gbé obinrin náà lọ. 16Ṣugbọn ilẹ̀ ran obinrin náà lọ́wọ́. Ilẹ̀ lanu, ó fa omi tí Ẹranko Ewèlè náà tu jáde lẹ́nu mu. 17Inú wá bí Ẹranko Ewèlè yìí sí obinrin náà. Ó wá lọ gbógun ti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọn ń jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu. 18Ó dúró lórí iyanrìn etí òkun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌFIHÀN 12: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀