ORIN DAFIDI 94
94
Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé
1OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san,
ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn!
2Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé;
san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn!
3OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?
Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní?
4Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù,
gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu.
5Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA,
wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú.
6Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò,
wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba;
7wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa;
Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.”
8Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,
ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!
Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n?
9Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?
Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran?
10Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,
ni kò ní jẹ yín níyà?
Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀?
11OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,
ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni.#1Kọr 3:20
12Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,
tí o sì kọ́ ní òfin rẹ,
13kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,
títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú.
14Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;
kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;
15nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,
àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
16Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?
Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi?
17Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,
ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú.
18Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,”
OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró.
19Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,
ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le.
20Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,
àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?
21Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo;
wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.
22Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi,
Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi.
23Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn,
yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn.
OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 94: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010