ORIN DAFIDI 91:3-13

ORIN DAFIDI 91:3-13 YCE

Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun. Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́, lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ. O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru, tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán, tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn, tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan. Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ; ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn, tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú. Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ, o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ, ibi kankan kò ní dé bá ọ, bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ, pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta. O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀; ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.