ORIN DAFIDI 8:3-6

ORIN DAFIDI 8:3-6 YCE

Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀– Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀? Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀? O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun, o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé. O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀