ORIN DAFIDI 47

47
Ọba Àwọn Ọba
1Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun.
2Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,
Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,
ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa.
4Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,
èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn.
5A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀,
a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè.
6Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn;
Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn!
7Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;
Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn!
8Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;
Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.
9Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ
pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu.
Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé;
òun ni ọlọ́lá jùlọ!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 47: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀