ORIN DAFIDI 44:9-26

ORIN DAFIDI 44:9-26 YCE

Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀, o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́. O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun; àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun. O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà, o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀, o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn. O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa; a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé. Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru, ìtìjú sì ti bò mí. Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára, lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san. Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ, sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko, o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa, tabi tí a bá bọ oriṣa, ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀? Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru, tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà. Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn? Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́? Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa? Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀; àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́. Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́! Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.