ORIN DAFIDI 42:1-4

ORIN DAFIDI 42:1-4 YCE

Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun. Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi, àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè. Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé? Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.