Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ; ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá, kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìwọ ni ibi ìsásí mi; o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro; o sì fi ìgbàlà yí mi ká. N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn; n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn; n óo sì máa mójútó ọ. Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka, tí kò ni ọgbọ́n ninu, tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nu kí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀. Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA; ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.
Kà ORIN DAFIDI 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 32:6-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò