Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.
Kà ORIN DAFIDI 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 27:4-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò