ORIN DAFIDI 27:3-4

ORIN DAFIDI 27:3-4 YCE

Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀.