ORIN DAFIDI 27:1-6

ORIN DAFIDI 27:1-6 YCE

OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi; ta ni n óo bẹ̀rù? OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóo bà mí? Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi, tí wọ́n fẹ́ pa mí, àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi, wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú. Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.