ORIN DAFIDI 22:23-24

ORIN DAFIDI 22:23-24 YCE

Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín! Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un, ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́; kò sì ṣá wọn tì, bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn, ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.