ORIN DAFIDI 22:1-3

ORIN DAFIDI 22:1-3 YCE

Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀, tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́? Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án, ṣugbọn o ò dáhùn; mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́. Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́, o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́.