ORIN DAFIDI 2

2
Àyànfẹ́ Ọlọrun
1Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù
tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?
2Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,
àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,
wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.
3Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já
kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.” #A. Apo 4:25-26
4Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;
OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.
5Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,
yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,
6Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,
ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”
7N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;
Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,
lónìí ni mo bí ọ.
8Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,
gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.
9Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,
o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.” #A. Apo 13:33; Heb 1:5; 5:5 #Ifi 2:26-27; 12:5; 19:15
10Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;
ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.
11Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,
ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.
12Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú,
kí ó má baà pa yín run lójijì;
nítorí a máa yára bínú.
Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀