ORIN DAFIDI 148:1-14

ORIN DAFIDI 148:1-14 YCE

Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ yìn ín lókè ọ̀run. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀. Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn. Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ; yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA, nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae; ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé, ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi; iná ati yìnyín, ati ìrì dídì, ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké, ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari; ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn, ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé; ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge, ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà. Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù; ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ. Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára, ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn; ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.