ORIN DAFIDI 138
138
Adura Ọpẹ́
1N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA,
lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ.
2Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,
n óo sì máa yin orúkọ rẹ,
nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,
nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ.#138:2d Ìtumọ̀ gbolohun yìí kò dáni lójú tó ní èdè Heberu.
3Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,
o sì fún mi ní agbára kún agbára.
4OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,
nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
5Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,
nítorí pé ògo OLUWA tóbi.
6Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,
ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,
ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.
7Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,
sibẹ, o dá mi sí;
o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,
o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí.
8OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi,
OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 138: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010