ORIN DAFIDI 119:49-64

ORIN DAFIDI 119:49-64 YCE

Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ, èyí tí ó fún mi ní ìrètí. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé: ìlérí rẹ mú mi wà láàyè. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi, ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́, OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀. Inú mi á máa ru, nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú, tí wọn ń rú òfin rẹ. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ, lákòókò ìrìn àjò mi láyé. Mo ranti orúkọ rẹ lóru; OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́: Èyí ni ìṣe mi: Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní; mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ, ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi, mo yipada sí ìlànà rẹ; mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi, n kò ní gbàgbé òfin rẹ. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́, nítorí ìlànà òdodo rẹ. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí, àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; kọ́ mi ní ìlànà rẹ.