ORIN DAFIDI 119:41-48

ORIN DAFIDI 119:41-48 YCE

Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn, nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá, nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae. N óo máa rìn fàlàlà, nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba, ojú kò sì ní tì mí. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ, nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.