Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ, kí n lè wà láàyè, kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu tí ó wà ninu òfin rẹ. Àlejò ni mí láyé, má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún, tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́. Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi, nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́. Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi, sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi, àwọn ni olùdámọ̀ràn mi. Mo di ẹni ilẹ̀, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. La òfin rẹ yé mi, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́, mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìwà èké jìnnà sí mi, kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ. Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́, mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ. Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó tì mí. N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́, nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.
Kà ORIN DAFIDI 119
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 119:17-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò