Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí, ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ, kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA, mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gidigidi. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ; gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA, fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ, pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ, nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà. Múra láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA; òfin rẹ sì ni inú dídùn mi. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́, sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù; wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí, nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.
Kà ORIN DAFIDI 119
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 119:161-176
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò