ORIN DAFIDI 119:113-136

ORIN DAFIDI 119:113-136 YCE

Mo kórìíra àwọn oníyèméjì, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi, mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi, kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè, má sì dójú ìrètí mi tì mí. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu, kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀, nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin, nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ. Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ, mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ, má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára. Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ, má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ, ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ. Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Iranṣẹ rẹ ni mí, fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ. OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan, nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ. Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà. Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké. Òfin rẹ dára, nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀, a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ, nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore bí o ti máa ń ṣe sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan, kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ; kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò, nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.