Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,
ninu àgọ́ àwọn olódodo.
“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.
A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,
ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!”
N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,
n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe.
OLUWA jẹ mí níyà pupọ,
ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,
kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,
kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA.
Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;
àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé.
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,
o sì ti di olùgbàlà mi.
Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,
ni ó di pataki igun ilé.
OLUWA ló ṣe èyí;
ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.
Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,
ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.
OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,
OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,
láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.
OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.
Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,
títí dé ibi ìwo pẹpẹ.
Ìwọ ni Ọlọrun mi,
n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.
Ìwọ ni Ọlọrun mi,
n óo máa gbé ọ ga.
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.