ORIN DAFIDI 112:1-9

ORIN DAFIDI 112:1-9 YCE

Ẹ yin OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA, tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀. Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé, a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin. Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀, Òdodo rẹ̀ wà títí lae. Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo. Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà. A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae, títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀. Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù, ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á, níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka, òdodo rẹ̀ wà títí lae, yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá.