Ẹ yin OLUWA! N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn, láàrin àwọn olódodo, ati ní àwùjọ àwọn eniyan. Iṣẹ́ OLUWA tóbi, àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri. Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo, òdodo rẹ̀ sì wà títí lae. OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀, a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae. Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀, nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà, gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú. Wọ́n wà títí lae ati laelae, ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin. Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀, ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé. Títí lae ni ìyìn rẹ̀.
Kà ORIN DAFIDI 111
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 111:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò