ORIN DAFIDI 110

110
OLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀
1OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé,
“Jókòó sí apá ọ̀tún mi,
títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”#Mat 22:44; Mak 12:36; Luk 20:42-43; A. Apo 2:34-35; 1 Kọr 15:25; Efe 1:20-22; Kol 3:1; Heb 1:13; 8:1; 10:12-13
2OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni.
O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ.
3Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀,
lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́.
Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀.
4OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé,
“Alufaa ni ọ́ títí lae,
nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.”#Heb 5:6; 6:20; 7:17, 21
5OLUWA wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
yóo rún àwọn ọba wómúwómú ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.
6Yóo ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
ọpọlọpọ òkú ni yóo sì sùn ninu wọn;
yóo sì run àwọn ìjòyè káàkiri ilẹ̀ ayé.
7Ọba yóo mu omi ninu odò ẹ̀bá ọ̀nà,
nítorí náà yóo sì gbé orí rẹ̀ sókè bí aṣẹ́gun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 110: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀