ORIN DAFIDI 107

107
Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀
1Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#1Kron 16:34; 2Kron 5:13; 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 100:5; 106:1; 118:1; 136:1; Jer 33:11
2Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀,
àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú,
3tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì,
láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn,
láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù.
4Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀,
wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.
5Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n,
ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú.
6Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn.
7Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde,
lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé.
8Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan.
9Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn,
ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.
10Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,
wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,
11nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun,
wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo.
12Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn,
wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́.
13Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,
ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.
14Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,
ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn.
15Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.
16Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,
ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá.
17Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn.
18Oúnjẹ rùn sí wọn,
wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú.
19Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,
ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.
20Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá,
ó tún kó wọn yọ ninu ìparun.
21Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.
22Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́,
kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀.
23Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi,
wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,
24wọ́n rí ìṣe OLUWA,
àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú.
25Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà,
tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè.
26Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro,
wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú,
jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà.
27Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí,
gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu.
28Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,
ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.
29Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró,
ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀.
30Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀,
ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.
31Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.
32Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan,
kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà.
33Ó sọ odò di aṣálẹ̀,
ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ,
34ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀,
nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
35Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi.
36Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,
wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé.
37Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,
wọ́n sì kórè lọpọlọpọ.
38Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,
kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.#Sir 39:33
39Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,
nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,
40ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,
ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,
níbi tí kò sí ọ̀nà.
41Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú,
ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran.
42Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,
a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.
43Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi;
kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 107: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀