ORIN DAFIDI 107:28-30

ORIN DAFIDI 107:28-30 YCE

Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀, ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.