ORIN DAFIDI 106:19-23

ORIN DAFIDI 106:19-23 YCE

Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu, wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà. Wọ́n gbé ògo Ọlọrun fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti, ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu, ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run, bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀, láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.