ORIN DAFIDI 103:8-12

ORIN DAFIDI 103:8-12 YCE

Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí, bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.