Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì. OLUWA a máa dáni láre a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo àwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli. Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí, bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.
Kà ORIN DAFIDI 103
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 103:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò