N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo, OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí. N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n; nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi? N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi. N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi. Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun. N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan. Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi, n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi, n óo pa á run, n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè.
Kà ORIN DAFIDI 101
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 101:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò