ÌWÉ ÒWE 5:1-6

ÌWÉ ÒWE 5:1-6 YCE

Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ, tẹ́tí rẹ sí òye mi, kí o baà lè ní làákàyè, kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀. Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ, ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ, ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú, ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè, ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.