ÌWÉ ÒWE 30:12-14

ÌWÉ ÒWE 30:12-14 YCE

Àwọn tí wọ́n mọ́ lójú ara wọn, ṣugbọn a kò tíì wẹ èérí wọn nù. Àwọn kan wà tí ojú wọ́n ga, lókè lókè ni ojú wọn wà. Àwọn kan wà tí eyín wọn dàbí idà, kìkì ọ̀bẹ ló kún èrìgì wọn, láti jẹ àwọn talaka run lórí ilẹ̀ ayé, ati láti pa àwọn aláìní run láàrin àwọn eniyan.