ÌWÉ ÒWE 2:1-11

ÌWÉ ÒWE 2:1-11 YCE

Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí o sì fi ọkàn sí òye, bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀, tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀, bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka, tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́, nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ. O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n, ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere. Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára, ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ, òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́