ÌWÉ ÒWE 16:31-33

ÌWÉ ÒWE 16:31-33 YCE

Adé ògo ni ewú orí, nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i. Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ. À máa ṣẹ́ gègé kí á lè mọ ìdí ọ̀ràn, ṣugbọn OLUWA nìkan ló lè pinnu ohunkohun.