ÌWÉ ÒWE 15:8-10

ÌWÉ ÒWE 15:8-10 YCE

Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA, ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú, ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo. Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere, ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.