ÌWÉ ÒWE 15:1-3

ÌWÉ ÒWE 15:1-3 YCE

Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè. Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀. Ojú OLUWA wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.