ÌWÉ ÒWE 14:17-19

ÌWÉ ÒWE 14:17-19 YCE

Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀, ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù. Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀. Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere, àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.