ÌWÉ ÒWE 14:1-18

ÌWÉ ÒWE 14:1-18 YCE

Ọlọ́gbọ́n obinrin a máa kọ́ ilé rẹ̀, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi ọwọ́ ara rẹ̀ tú tirẹ̀ palẹ̀. Ẹni tí ń rìn pẹlu òótọ́ inú yóo bẹ̀rù OLUWA, ṣugbọn ẹni tí ń rin ìrìn ségesège yóo kẹ́gàn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ dàbí pàṣán ní ẹ̀yìn ara rẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó. Níbi tí kò bá sí mààlúù tí ń tu ilẹ̀, kò lè sí oúnjẹ, ṣugbọn agbára ọpọlọpọ mààlúù níí mú ọpọlọpọ ìkórè wá. Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́, ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké. Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i, ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye. Yẹra fún òmùgọ̀, nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀. Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n ni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀, ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ. Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà, ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere. Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀, kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀. Ìdílé ẹni ibi yóo parun, ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan, ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni. Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn, ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀. Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀. Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ. Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi, ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà. Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀, ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù. Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀.