NỌMBA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Nọmba ṣe àtúpalẹ̀ ìtàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli ninu ìrìn àjò wọn láàrin ogoji ọdún láti ìgbà tí wọ́n ti kúrò ní orí òkè Sinai títí tí wọ́n fi dé ibodè ilẹ̀ tí Ọlọrun ti ṣèlérí fún wọn. Àkọlé ìwé náà ṣe ìtọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ pataki kan tí ó ṣẹ̀ ní àkókò ìrìn àjò náà; ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ètò ìkànìyàn tí Mose ṣe lórí òkè Sinai kí wọ́n tó tẹ̀síwájú ninu ìrìn àjò wọn. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, wọ́n tún ṣe ètò ìkànìyàn mìíràn ní Moabu tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jọdani. Ní àkókò tó wà láàrin ètò ìkànìyàn mejeeji, àwọn ọmọ Israẹli gbìyànjú ati gba Kadeṣi Banea tí ó wà ní ìhà gúsù ibodè Kenaani, ṣugbọn wọn kò lè dé ilẹ̀ ìlérí náà. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún tí wọ́n ti ń gbé agbègbè ibẹ̀, wọ́n ṣí lọ sí ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, àwọn kan tẹ̀dó sibẹ àwọn yòókù sì la inú odò náà kọjá lọ sí Kenaani.
Ìwé Nọmba ṣe àkójọpọ̀ ìtàn àwọn eniyan tí wọn kì í pẹ́ ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, wọn kì í lè kojú ìṣòro pẹlu ẹ̀mí ìgboyà, wọn a máa ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun, ati sí Mose, tí Ọlọrun yàn, láti máa darí wọn. Ìtàn inú ìwé yìí fihàn pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun kì í yẹ̀, a sì máa dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan náà jẹ́ eniyan burúkú ati aláìgbọràn ẹ̀dá. A rí Mose bí ẹni tí ó ní ẹ̀mí ìdúróṣinṣin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onínúfùfù ni, ó fi gbogbo ara sin Ọlọrun ati àwọn eniyan rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àwọn ọmọ Israẹli palẹ̀mọ́ láti kúrò ní orí Òkè Sinai 1:1–9:23
a. Ètò ìkànìyàn àkọ́kọ́ 1:1–4:49
b. Àwọn oríṣìíríṣìí òfin ati ìlànà 5:1–8:26
d. Àjọ Ìrékọjá keji 9:1-23
Ìrìn àjò láti orí òkè Sinai dé Moabu 10:1–21:35
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ ní Moabu 22:1–32:42
Àlàyé ṣókí lórí ìrìn àjò láti Ijipti títí dé Moabu 33:1-49
Àwọn ìlànà tí Ọlọrun fi lélẹ̀ fún wọn láti tẹ̀lé kí wọ́n tó rékọjá odò Jọdani 33:50–36:13

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀