NEHEMAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀nà mẹrin pataki ni a lè pín ìtàn inú Ìwé Nehemaya sí: (1) Ọba Pasia dá Nehemaya pada sí Jerusalẹmu ó fi jẹ gomina Juda. (2) Wọ́n tún odi Jerusalẹmu mọ. (3) Ẹsira fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ati tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ka òfin Ọlọrun, àwọn eniyan sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (4) Àwọn nǹkan mìíràn tí Nehemaya gbé ṣe gẹ́gẹ́ bíi gomina Juda.
Nǹkan pataki tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìwé yìí ni àkọsílẹ̀ nípa bí Nehemaya ṣe gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ati bí ó ṣe máa ń gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Nehemaya pada sí Jerusalẹmu 1:1–2:20
Wọ́n tún odi Jerusalẹmu mọ 3:1–7:73
Kíka òfin ati títún majẹmu dá 8:1–10:39
Àwọn nǹkan mìíràn tí Nehemaya ṣe 11:1–13:31
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NEHEMAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010