Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko. Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta. Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila. Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000).
Kà MAKU 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MAKU 6:39-44
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò