MAKU 12:1-17

MAKU 12:1-17 YCE

Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn. Ṣugbọn nínà ni wọ́n nà án, wọ́n bá lé e pada ní ọwọ́ òfo. Ó tún rán ẹrú mìíràn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n lu òun lórí ní àlùbẹ́jẹ̀, wọ́n sì dójú tì í. Nígbà tí ó rán ẹrú mìíràn lọ, pípa ni wọ́n pa á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọpọlọpọ àwọn ẹrú mìíràn, wọ́n lu àwọn kan, wọ́n pa àwọn mìíràn. Ó wá ku ẹnìkan tíí ṣe àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni ó rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọn yóo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn àwọn alágbàro náà wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ jẹ́ tiwa.’ Nígbà náà ni wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n bá wọ́ ọ jù sẹ́yìn ọgbà àjàrà. “Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóo ṣe? Yóo wá, yóo pa àwọn alágbàro wọ̀n-ọn-nì, yóo sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàro mìíràn. Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́, pé, ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀ ni ó di pataki igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, Ìyanu ni ó jẹ́ ní ojú wa.’ ” Àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin ati àwọn àgbà ń wá ọ̀nà láti mú un, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ. Wọ́n rán àwọn kan ninu àwọn Farisi ati àwọn ọ̀rẹ́ Hẹrọdu sí i láti lọ gbọ́ tẹnu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, sọ fún wa, ṣé ó tọ̀nà pé kí á máa san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?” Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadaka kan wá fún mi kí n rí i.” Wọ́n fún un ní ọ̀kan. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ó wà ní ara rẹ̀ yìí?” Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi nǹkan tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Ọlọrun, ẹ fi fún Ọlọrun.” Ẹnu yà wọ́n pupọ sí ìdáhùn rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ