MATIU 6:24-27

MATIU 6:24-27 YCE

“Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún máa bọ owó. “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ tabi kí ni ẹ óo mu, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora. Mo ṣebí ẹ̀mí yín ju oúnjẹ lọ; ati pé ara yín ju aṣọ lọ. Ẹ wo àwọn ẹyẹ lójú ọ̀run. Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó nǹkan oko jọ sinu abà. Sibẹ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Mo ṣebí ẹ̀yin sàn ju àwọn ẹyẹ lọ! Ta ni ninu yín tí ó lè ṣe àníyàn títí tí ó lè fi kún ọjọ́ ayé rẹ̀?

Àwọn fídíò fún MATIU 6:24-27

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú MATIU 6:24-27