“Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú, nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín máa dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wolii tí ó ti wà ṣiwaju yín.
Kà MATIU 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 5:3-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò