MATIU 4:18-21

MATIU 4:18-21 YCE

Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.” Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n.

Àwọn fídíò fún MATIU 4:18-21