Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá. Kò sí níhìn-ín, nítorí ó ti jí dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.” Àwọn obinrin náà bá yára kúrò níbi ibojì náà pẹlu ìbẹ̀rùbojo ati ayọ̀ ńlá, wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
Kà MATIU 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 28:5-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò