MATIU 21:28-46

MATIU 21:28-46 YCE

Ó wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ rò nípa èyí? Ọkunrin kan ní ọmọ meji. Ó lọ sọ́dọ̀ ekinni, ó sọ fún un pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà mi lónìí.’ Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘N kò ní lọ.’ Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó ronupiwada, ó bá lọ. Ọkunrin náà lọ sọ́dọ̀ ọmọ keji, ó sọ fún un bí ó ti sọ fún ekinni. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘Ó dára, mo gbọ́, Baba!’ Ṣugbọn kò lọ. Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?” Wọ́n ní, “Ekinni ni.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun. Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.” Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò ìkórè, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ sí àwọn alágbàro náà láti gba ìpín tirẹ̀ wá ninu èso rẹ̀. Ṣugbọn àwọn alágbàro náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n na àwọn kan, wọ́n pa àwọn kan, wọ́n sọ àwọn mìíràn ní òkúta. Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn. Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’ Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.” Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, ‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki ní igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’ “Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [ Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”] Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí. Wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí àwọn eniyan gbà á bíi wolii.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ